Native Bible

John 18:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá, nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”

John 18:39 in English

John 18:39 · Berean Standard Bible

But it is your custom that I release to you one prisoner at the Passover. So then, do you want me to release to you the King of the Jews?”

Context

37Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Ọba ni ọ́ nígbà náà?” Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.” 38Pilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀. 39Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá, nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?” 40Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.