Native Bible

John 18:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Simoni Peteru sì ń tọ Jesu lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jesu wọ ààfin olórí àlùfáà lọ.

John 18:15 in English

John 18:15 · Berean Standard Bible

Now Simon Peter and another disciple were following Jesus. Since that disciple was known to the high priest, he also went with Jesus into the courtyard of the high priest.

Context

13Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Annasi; nítorí òun ni àna Kaiafa, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà. 14Kaiafa sá à ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfààní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn. 15Simoni Peteru sì ń tọ Jesu lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jesu wọ ààfin olórí àlùfáà lọ. 16Ṣùgbọ́n Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùṣọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Peteru wọlé. 17Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?” Ó wí pé, “Èmi kọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.