Johanu 18:12
John 18:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀ṣọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jesu, wọ́n sì dè é.
John 18:12 in English
John 18:12 · Berean Standard Bible
Then the band of soldiers, with its commander and the officers of the Jews, arrested Jesus and bound Him.
Context
10Nígbà náà ni Simoni Peteru ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Orúkọ ìránṣẹ́ náà a máa jẹ́ Makọọsi. 11Nítorí náà Jesu wí fún Peteru pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ, ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?” 12Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀ṣọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jesu, wọ́n sì dè é. 13Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Annasi; nítorí òun ni àna Kaiafa, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà. 14Kaiafa sá à ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfààní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.