Johanu 16:2
John 16:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sinagọgu: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run.
John 16:2 in English
John 16:2 · Berean Standard Bible
They will put you out of the synagogues. In fact, a time is coming when anyone who kills you will think he is offering a service to God.
Context
1“Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má ba à mú yín yapa kúrò. 2Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sinagọgu: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run. 3Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí. 4Ṣùgbọ́n nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, pé nígbà tí wákàtí wọn bá dé, kí ẹ lè rántí wọn pé mo ti wí fún yín. Ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan wọ̀nyí fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, nítorí tí mo wà pẹ̀lú yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.