Johanu 15:21
John 15:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n yóò ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi.
John 15:21 in English
John 15:21 · Berean Standard Bible
But they will treat you like this because of My name, since they do not know the One who sent Me.
Context
19Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ yin bi àwọn tirẹ̀; gẹ́gẹ́ bi o ṣe ri tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín. 20Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa tiyín mọ́ pẹ̀lú. 21Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n yóò ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi. 22Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 23Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.