Johanu 15:13
John 15:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.
John 15:13 in English
John 15:13 · Berean Standard Bible
Greater love has no one than this, that he lay down his life for his friends.
Context
11Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ayọ̀ mi kí ó lè wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín kí ó lè kún. 12Èyí ni òfin mi, pé kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín. 13Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. 14Ọ̀rẹ́ mi ni ẹ̀yin ń ṣe, bí ẹ bá ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún yín. 15Èmi kò pè yín ní ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́; nítorí ọmọ ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí olúwa rẹ̀ ń ṣe, ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́ nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fihàn fún yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.