Native Bible

John 12:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i.

John 12:17 in English

John 12:17 · Berean Standard Bible

Meanwhile, many people continued to testify that they had been with Jesus when He called Lazarus from the tomb and raised him from the dead.

Context

15“Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Sioni; wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá, o jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” 16Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i. 17Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i. 18Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí. 19Nítorí náà àwọn Farisi wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.