Native Bible

John 12:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú.

John 12:1 in English

John 12:1 · Berean Standard Bible

Six days before the Passover, Jesus came to Bethany, the hometown of Lazarus, whom He had raised from the dead.

Context

1Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. 2Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀. Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́, ṣùgbọ́n Lasaru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 3Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òsùwọ̀n lita kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.