Native Bible

John 11:52 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó fọ́nká kiri, kí ó le kó wọn papọ̀, kí ó sì sọ wọ́n di ọ̀kan.

John 11:52 in English

John 11:52 · Berean Standard Bible

and not only for the nation, but also for the scattered children of God, to gather them together into one.

Context

50Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó ṣàǹfààní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má ba à ṣègbé.” 51Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jesu yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà, 52kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó fọ́nká kiri, kí ó le kó wọn papọ̀, kí ó sì sọ wọ́n di ọ̀kan. 53Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. 54Nítorí náà Jesu kò rìn ní gbangba láàrín àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbèríko kan tí ó súnmọ́ aginjù, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Efraimu, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.