Johanu 11:5
John 11:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru.
John 11:5 in English
John 11:5 · Berean Standard Bible
Now Jesus loved Martha and her sister and Lazarus.
Context
3Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.” 4Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” 5Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru. 6Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà. 7Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.