Johanu 11:47
John 11:47 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ. Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì.
John 11:47 in English
John 11:47 · Berean Standard Bible
Then the chief priests and Pharisees convened the Sanhedrin * and said, “What are we to do? This man is performing many signs.
Context
45Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Maria, tí wọ́n rí ohun tí Jesu ṣe, ṣe gbà á gbọ́. 46Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisi lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jesu ṣe. 47Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ.
Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì. 48Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́, àwọn ará Romu yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.” 49Ṣùgbọ́n Kaiafa, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.