Native Bible

John 11:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu kò tí ì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Marta ti pàdé rẹ̀.

John 11:30 in English

John 11:30 · Berean Standard Bible

Now Jesus had not yet entered the village, but was still at the place where Martha had met Him.

Context

28Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” 29Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 30Jesu kò tí ì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Marta ti pàdé rẹ̀. 31Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Maria tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣe bí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀. 32Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.