Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán.

Jeremiah 7:22 in English

Jeremiah 7:22 · Berean Standard Bible

For when I brought your fathers out of the land of Egypt, I did not merely command them about burnt offerings and sacrifices,

Context

20“ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, “Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èso orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa.” 21“ ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Tẹ̀síwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yòókù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnra yín. 22Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán. 23Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé; gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín. 24Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetísílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀síwájú wọ́n ń rẹ̀yìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.