Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn. Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.

Jeremiah 52:9 in English

Jeremiah 52:9 · Berean Standard Bible

The Chaldeans seized the king and brought him up to the king of Babylon at Riblah in the land of Hamath, where he pronounced judgment on Zedekiah.

Context

7Bákan náà, odi ìlú náà ti ya àwọn ọmọ-ogun sì tí sálọ. Wọn fi ìlú náà sílẹ̀ ní òru nípa ojú ọ̀nà tó wà láàrín odi méjèèjì lẹ́bàá ọgbà ọba. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn ará Babeli yìí yí ìlú náà ká. Wọ́n sá gba aginjù lọ. 8Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ogun Babeli lépa ọba Sedekiah wọ́n sì le bá ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun sì pínyà, kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ wọ́n sì túká. 9Wọ́n sì mu ní ìgbèkùn. Wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati níbẹ̀ ni ó ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 10Ní Ribla ni ọba Babeli ti pa ọmọkùnrin Sedekiah lójú rẹ̀; ó sì tún pa gbogbo àwọn aláṣẹ Juda. 11Lẹ́yìn náà, ọba Babeli yọ Sedekiah ní ojú, o sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì gbe e lọ sí Babeli níbi tí ó ti fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.