Jeremiah 44:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀.
Jeremiah 44:3 in English
Jeremiah 44:3 · Berean Standard Bible
because of the evil they have done. They provoked Me to anger by continuing to burn incense and to serve other gods that neither they nor you nor your fathers ever knew.
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti: 2“Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun. 3Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀. 4Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’ 5Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.