Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dájúdájú, à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe. A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run, à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà náà àwa ní oúnjẹ púpọ̀, a sì ṣe rere a kò sì rí ibi.

Jeremiah 44:17 in English

Jeremiah 44:17 · Berean Standard Bible

Instead, we will do everything we vowed to do: We will burn incense to the Queen of Heaven and offer drink offerings to her, just as we, our fathers, our kings, and our officials did in the cities of Judah and in the streets of Jerusalem. At that time we had plenty of food and good things, and we saw no disaster.

Context

15Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremiah. 16“Wọn sì wí pé, àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ní orúkọ Olúwa. 17Dájúdájú, à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe. A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run, à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà náà àwa ní oúnjẹ púpọ̀, a sì ṣe rere a kò sì rí ibi. 18Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí Ayaba Ọ̀run àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.” 19Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.