Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò gbé ogun sí Ejibiti; yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú; ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà.

Jeremiah 43:11 in English

Jeremiah 43:11 · Berean Standard Bible

He will come and strike down the land of Egypt, bringing death to those destined for death, captivity to those destined for captivity, and the sword to those destined for the sword.

Context

9“Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu-ọ̀nà ààfin Farao ní Tafanesi. 10Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí. Èmi yóò ránṣẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli, Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ. 11Yóò gbé ogun sí Ejibiti; yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú; ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà. 12Yóò dá, iná sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sì mú wọn lọ ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn, yóò ró aṣọ rẹ̀ mọ́ra, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò ró Ejibiti òun yóò sì lọ kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà. 13Ní tẹmpili ni yóò ti fọ́ ère ilé oòrùn tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti túútúú, yóò sì sun àwọn tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.