Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti ṣe.

Jeremiah 41:11 in English

Jeremiah 41:11 · Berean Standard Bible

When Johanan son of Kareah and all the commanders of the armies with him heard of all the crimes that Ishmael son of Nethaniah had committed,

Context

9Nísinsin yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Gedaliah sí ni ọba Asa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí ọba Baaṣa ti Israẹli. Iṣmaeli ọmọ Netaniah sì ti kó òkú kún inú rẹ̀. 10Iṣmaeli sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mispa nígbèkùn, ọmọbìnrin ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tókù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti fi yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ṣe olórí. Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ammoni. 11Nígbà tí Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti ṣe. 12Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Iṣmaeli ọmọ Netaniah jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gibeoni. 13Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Iṣmaeli tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Johanani ọmọkùnrin Karea àti àwọn olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.