Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremiah, ó sọ fún un wí pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi.

Jeremiah 40:2 in English

Jeremiah 40:2 · Berean Standard Bible

The captain of the guard found Jeremiah and said to him, “The LORD your God decreed this disaster on this place,

Context

1Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rama. Ó rí Jeremiah tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jerusalẹmu àti Juda. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli. 2Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremiah, ó sọ fún un wí pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi. 3Nísinsin yìí, Olúwa ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí Olúwa, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀. 4Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lé mi ká lọ sí Babeli, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, dúró síbí. Wò ó, gbogbo orílẹ̀-èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.