Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Johanani ọmọkùnrin ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí ó kù ní orílẹ̀-èdè sì tọ Gedaliah wá ní Mispa.

Jeremiah 40:13 in English

Jeremiah 40:13 · Berean Standard Bible

Meanwhile, Johanan son of Kareah and all the commanders of the armies in the field came to Gedaliah at Mizpah

Context

11Nígbà tí gbogbo àwọn Juda ní Moabu, Ammoni, Edomu àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ pé ọba Babeli ti fi ohun tókù sílẹ̀ ní Juda, àti pé ó ti yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ọmọkùnrin Ṣafani gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn. 12Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ Juda sọ́dọ̀ Gedaliah ní Mispa láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí. Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èso igi. 13Johanani ọmọkùnrin ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí ó kù ní orílẹ̀-èdè sì tọ Gedaliah wá ní Mispa. 14Wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ha mọ̀ pé Baalisi ọba àwọn Ammoni ti rán Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah láti lọ mú ẹ̀mí rẹ?” Ṣùgbọ́n Gedaliah ọmọkùnrin ti Ahikamu kò gbà wọ́n gbọ́. 15Nígbà náà ni Johanani ọmọkùnrin Karea sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún Gedaliah ní Mispa pé, “Jẹ́ kí èmi lọ pa Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí. Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù Juda sì parun?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.