Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán? Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ; wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.

Jeremiah 4:30 in English

Jeremiah 4:30 · Berean Standard Bible

And you, O devastated one, what will you do, though you dress yourself in scarlet, though you adorn yourself with gold jewelry, though you enlarge your eyes with paint? You adorn yourself in vain; your lovers despise you; they want to take your life.

Context

28Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún àwọn ọ̀run lókè yóò ṣú òòkùn nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀ mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.” 29Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà gbogbo ìlú yóò sálọ. Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó; ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ. Gbogbo ìlú náà sì di ahoro; kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀. 30Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán? Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ; wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ. 31Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí, tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ ọmọbìnrin Sioni tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀. Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé, “Kíyèsi i mo gbé, nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.