Jeremiah 38:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, ‘Sọ fún wa ohun tí o bá ọba sọ tàbí ohun tí ọba sọ fún ọ; má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́,’
Jeremiah 38:25 in English
Jeremiah 38:25 · Berean Standard Bible
If the officials hear that I have spoken with you, and they come and demand of you, ‘Tell us what you said to the king and what he said to you; do not hide it from us, or we will kill you,’
Context
23“Wọn yóò kó àwọn ìyàwó àti ọmọ rẹ wá sí Babeli. Ìwọ gan an kò ní bọ́ níbẹ̀, ọba Babeli yóò mú ọ, wọn yóò sì jó ìlú yìí kanlẹ̀.” 24Nígbà náà ni Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, tàbí kí o kú. 25Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, ‘Sọ fún wa ohun tí o bá ọba sọ tàbí ohun tí ọba sọ fún ọ; má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́,’ 26nígbà náà kí o sọ fún wọn, ‘Mò ń bẹ ọba láti má jẹ́ kí n padà lọ sí ilé Jonatani láti lọ kú síbẹ̀.’ ” 27Gbogbo àwọn olóyè sì wá sí ọ̀dọ̀ Jeremiah láti bi í léèrè, ó sì sọ gbogbo ohun tí ọba ní kí ó sọ. Wọn kò sì sọ ohunkóhun mọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí òun àti ọba jọ sọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.