Jeremiah 38:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ, èyí ni ohun tí Olúwa ti fihàn mí.
Jeremiah 38:21 in English
Jeremiah 38:21 · Berean Standard Bible
But if you refuse to surrender, this is the word that the LORD has shown me:
Context
19Ọba Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Mò ń bẹ̀rù àwọn Júù tó ti sálọ sí ilẹ̀ Babeli, nítorí pé àwọn ará Babeli lè fà mí lé wọn lọ́wọ́ láti fìyà jẹ mí.” 20Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Wọn kò ní fi ọ́ lé e lọ́wọ́. Pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ nípa ṣíṣe ohun tí mo sọ fún ọ; yóò sì dára fún ọ, ẹ̀mí rẹ yóò sì wà. 21Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ, èyí ni ohun tí Olúwa ti fihàn mí. 22Gbogbo àwọn obìnrin tókù ní ààfin ọba Juda ni wọn yóò kó jáde fún àwọn ìjòyè ọba Babeli. Àwọn obìnrin náà yóò sì sọ fún ọ pé:
“ ‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàn ọ́ jẹ,
wọ́n sì borí rẹ.
Ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀;
àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fi ọ́ sílẹ̀.’ 23“Wọn yóò kó àwọn ìyàwó àti ọmọ rẹ wá sí Babeli. Ìwọ gan an kò ní bọ́ níbẹ̀, ọba Babeli yóò mú ọ, wọn yóò sì jó ìlú yìí kanlẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.