Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Babeli yóò yè; yóò sá àsálà, yóò sì yè.’

Jeremiah 38:2 in English

Jeremiah 38:2 · Berean Standard Bible

“This is what the LORD says: Whoever stays in this city will die by sword and famine and plague, but whoever surrenders to the Chaldeans * will live; he will retain his life like a spoil of war, and he will live.

Context

1Ṣefatia ọmọ Mattani, Gedaliah ọmọ Paṣuri, Jehukali ọmọ Ṣelemiah, àti Paṣuri ọmọ Malkiah, gbọ́ ohun tí Jeremiah ń sọ fún àwọn ènìyàn nígbà tí ó sọ wí pé, 2“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Babeli yóò yè; yóò sá àsálà, yóò sì yè.’ 3Àti pé èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ìdánilójú wà wí pé a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun ọba Babeli; tí yóò sì kó wa nígbèkùn.’ ” 4Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún ọba pé, “Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí; ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ-ogun tókù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn. Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ìre fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.