Jeremiah 38:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jeremiah sì sọ fún Sedekiah pé, “Tí mo bá fún ọ ní èsì, ṣé o kò nípa mí? Tí mo bá gbà ọ́ nímọ̀ràn, o kò ní gbọ́ tèmi.”
Jeremiah 38:15 in English
Jeremiah 38:15 · Berean Standard Bible
“If I tell you,” Jeremiah replied, “you will surely put me to death. And even if I give you advice, you will not listen to me.”
Context
13Báyìí ni wọ́n ṣe fi okùn yọ Jeremiah jáde, wọ́n sì mu un gòkè láti inú ihò wá, Jeremiah sì wà ní àgbàlá ilé túbú. 14Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ pe, Jeremiah òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnu ibodè kẹta nílé Olúwa. Ọba sì sọ fún Jeremiah pé, “Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan; má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi.” 15Jeremiah sì sọ fún Sedekiah pé, “Tí mo bá fún ọ ní èsì, ṣé o kò nípa mí? Tí mo bá gbà ọ́ nímọ̀ràn, o kò ní gbọ́ tèmi.” 16Ṣùgbọ́n ọba Sedekiah búra ní ìkọ̀kọ̀ fún Jeremiah wí pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀mí, èmi kò nípa ọ́ tàbí fà ọ́ fún àwọn tó ń lépa ẹ̀mí rẹ.” 17Nígbà náà ni Jeremiah sọ fún Sedekiah pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Àyàfi bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn olóyè ọba Babeli, a ó dá ẹ̀mí rẹ sí àti pé ìlú yìí kò ní di jíjó ní iná; ìwọ àti ilé rẹ yóò sì wà láààyè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.