Jeremiah 37:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín wí pé ọba Babeli kò ní gbóguntì yín wá?
Jeremiah 37:19 in English
Jeremiah 37:19 · Berean Standard Bible
Where are your prophets who prophesied to you, claiming, ‘The king of Babylon will not come against you or this land’?
Context
17Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?”
Jeremiah fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Babeli.” 18Nígbà náà, Jeremiah sọ fún ọba Sedekiah pé, “Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú? 19Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín wí pé ọba Babeli kò ní gbóguntì yín wá? 20Ṣùgbọ́n ní báyìí, olúwa mi ọba, èmí bẹ̀ ọ. Jẹ́ kí n mú ẹ̀dùn ọkàn mi tọ̀ ọ́ wá; má ṣe rán mi padà sí ilé Jonatani akọ̀wé, àfi kí n kú síbẹ̀.” 21Ọba Sedekiah wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremiah sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà tó wà ní ìlú yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremiah wà nínú àgbàlá náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.