Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà ni àwọn ìjòyè ṣe bínú sí Jeremiah, wọ́n jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n tún fi sí túbú nílé Jonatani akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú.

Jeremiah 37:15 in English

Jeremiah 37:15 · Berean Standard Bible

The officials were angry with Jeremiah, and they beat him and placed him in jail in the house of Jonathan the scribe, for it had been made into a prison.

Context

13Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu ibodè Benjamini, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Irijah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Hananiah mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń fi ara mọ́ àwọn ará Babeli.” 14Jeremiah sọ wí pé, “Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Babeli.” Ṣùgbọ́n Irijah ko gbọ́ tirẹ̀, dípò èyí a mú Jeremiah, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè. 15Nítorí náà ni àwọn ìjòyè ṣe bínú sí Jeremiah, wọ́n jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n tún fi sí túbú nílé Jonatani akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú. 16Wọ́n fi Jeremiah sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́. 17Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?” Jeremiah fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Babeli.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.