Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá lẹ́yìn ìgbà tí ọba Sedekiah ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú.

Jeremiah 34:8 in English

Jeremiah 34:8 · Berean Standard Bible

After King Zedekiah had made a covenant with all the people in Jerusalem to proclaim liberty, the word came to Jeremiah from the LORD

Context

6Nígbà náà ni Jeremiah wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekiah ọba Juda ní Jerusalẹmu. 7Nígbà tí ogun ọba Babeli ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní Juda, Lakiṣi, Aseka; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Juda. 8Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá lẹ́yìn ìgbà tí ọba Sedekiah ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú. 9Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Heberu lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Juda arákùnrin rẹ̀ sìn. 10Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbèkùn mọ́. Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.