Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèsè fún wọn.’

Jeremiah 33:9 in English

Jeremiah 33:9 · Berean Standard Bible

So this city will bring Me renown, joy, praise, and glory before all the nations of the earth, who will hear of all the good I do for it. They will tremble in awe because of all the goodness and prosperity that I will provide for it.

Context

7Èmi ó mú Juda àti Israẹli kúrò nínú ìgbèkùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀. 8Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sí mi. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedéédéé wọn sí mi jì wọ́n. 9Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèsè fún wọn.’ 10“Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ‘Ẹ̀yin yóò wí nípa ibí yìí pé, “Ó dahoro, láìsí ènìyàn tàbí ẹran.” Síbẹ̀ ní ìlú Juda àti ní òpópónà Jerusalẹmu tí ó dahoro, láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; ìbá à se ènìyàn tàbí ẹran, tí yóò gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí. 11Ariwo ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé Olúwa wí pé: “ ‘ “Yin Olúwa àwọn ọmọ-ogun, nítorí Olúwa dára, ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.” Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀,’ ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.