Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé:

Jeremiah 33:23 in English

Jeremiah 33:23 · Berean Standard Bible

Moreover, the word of the LORD came to Jeremiah:

Context

21Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dafidi ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dafidi kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22Èmi ó mú àwọn ọmọ lẹ́yìn Dafidi ìránṣẹ́ mi àti Lefi tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú Òkun tí kò ṣe é wọ́n.’ ” 23Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 24“Ǹjẹ́ ìwọ kò kíyèsi pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń sọ pé: ‘Olúwa ti kọ àwọn ọba méjèèjì tí ó yàn sílẹ̀’? Nítorí náà, ni wọ́n ti ṣe kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi. Wọn kò sì mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan. 25Báyìí ni Olúwa wí: ‘Bí èmi kò bá ti da májẹ̀mú mi pẹ̀lú ọ̀sán àti òru àti pẹ̀lú òfin ọ̀run àti ayé tí kò lè yẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.