Jeremiah 33:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́.
Jeremiah 33:20 in English
Jeremiah 33:20 · Berean Standard Bible
“This is what the LORD says: If you can break My covenant with the day and My covenant with the night, so that day and night cease to occupy their appointed time,
Context
18Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà tí ó jẹ́ ọmọ Lefi kò ní kùnà láti ní ọkùnrin kan tí ó dúró níwájú mi ní gbogbo ìgbà láti rú ẹbọ sísun; ẹbọ jíjẹ àti láti pèsè ìrúbọ.’ ” 19Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá wí pé: 20“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Tí ìwọ bá lè dá májẹ̀mú mi ní òru tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀sán àti òru kò lè sí ní àkókò wọn mọ́. 21Nígbà náà ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú Dafidi ìránṣẹ́ mi àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi tí ó jẹ́ àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ níwájú mi lè bàjẹ́, tí Dafidi kò sì rí ẹni láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22Èmi ó mú àwọn ọmọ lẹ́yìn Dafidi ìránṣẹ́ mi àti Lefi tí ó jẹ́ oníwàásù níwájú mi di bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí kò ṣe é kà àti bí iyẹ̀pẹ̀ ojú Òkun tí kò ṣe é wọ́n.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.