Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti tí ó wà ní ilẹ̀ Benjamini, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí.

Jeremiah 32:8 in English

Jeremiah 32:8 · Berean Standard Bible

Then, as the LORD had said, my cousin Hanamel came to me in the courtyard of the guard and urged me, ‘Please buy my field in Anathoth in the land of Benjamin, for you own the right of inheritance and redemption. Buy it for yourself.’” Then I knew that this was the word of the LORD.

Context

6Jeremiah wí pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 7Hanameli ọmọkùnrin Ṣallumu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó súnmọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’ 8“Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti tí ó wà ní ilẹ̀ Benjamini, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí. 9Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Anatoti láti ọwọ́ Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Mo sì wọn ìwọ̀n ṣékélì àti fàdákà mẹ́tàdínlógún fún un. 10Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí sí i, mo sì wọn fàdákà náà lórí òsùwọ̀n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.