Jeremiah 29:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ìre ìlú, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ìre ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.”
Jeremiah 29:7 in English
Jeremiah 29:7 · Berean Standard Bible
Seek the prosperity of the city to which I have sent you as exiles. Pray to the LORD on its behalf, for if it prospers, you too will prosper.”
Context
5“Ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín. 6Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fún ọkọ. Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ẹ máa pọ̀ sí i ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá. 7Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ìre ìlú, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ìre ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.” 8Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: “Ẹ má ṣe gbà kí àwọn wòlíì èké àti àwọn aláfọ̀ṣẹ àárín yín tàn yín jẹ. Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí àlá, èyí tí ẹ gbà wọ́n níyànjú láti lá. 9Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín lórúkọ mi, Èmi kò rán wọn níṣẹ́,” ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.