Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananiah ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremiah wí pé:

Jeremiah 28:12 in English

Jeremiah 28:12 · Berean Standard Bible

But shortly after Hananiah the prophet had broken the yoke off his neck, the word of the LORD came to Jeremiah:

Context

10Wòlíì Hananiah gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremiah kúrò, ó sì fọ́ ọ. 11Hananiah sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni Èmi yóò fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadnessari, ọba Babeli láàrín ọdún méjì.’ ” Wòlíì Jeremiah sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ. 12Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananiah ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremiah wí pé: 13“Lọ sọ fún Hananiah, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní ààyè wọn, wà á bá àjàgà onírin. 14Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi yóò fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè láti lè máa sin Nebukadnessari ọba Babeli, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Èmi yóò tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.