Jeremiah 26:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremiah tí ó sọ ní ilé Olúwa.
Jeremiah 26:7 in English
Jeremiah 26:7 · Berean Standard Bible
Now the priests and prophets and all the people heard Jeremiah speaking these words in the house of the LORD,
Context
5àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́), 6nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ” 7Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremiah tí ó sọ ní ilé Olúwa. 8Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremiah ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí Olúwa pàṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dìímú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú! 9Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa pé, ilé yìí yóò dàbí Ṣilo, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremiah nínú ilé Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.