Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ọba Jehoiakimu àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Uriah gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Ejibiti.

Jeremiah 26:21 in English

Jeremiah 26:21 · Berean Standard Bible

King Jehoiakim and all his mighty men and officials heard his words, and the king sought to put him to death. But when Uriah found out about it, he fled in fear and went to Egypt.

Context

19Ǹjẹ́ Hesekiah ọba Juda tàbí ẹnikẹ́ni ní Juda pa á bí? Ǹjẹ́ Hesekiah kò bẹ̀rù Olúwa tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ Olúwa kò ha a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.” 20(Bákan náà Uriah ọmọ Ṣemaiah láti Kiriati-Jearimu jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ Olúwa. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremiah ti ṣe. 21Nígbà tí ọba Jehoiakimu àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Uriah gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Ejibiti. 22Ọba Jehoiakimu rán Elnatani ọmọ Akbori lọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn. 23Wọ́n sì mú Uriah láti Ejibiti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Jehoiakimu; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.)

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.