Jeremiah 25:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jerusalẹmu àti àwọn ìlú Juda, àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.
Jeremiah 25:18 in English
Jeremiah 25:18 · Berean Standard Bible
to make them a ruin, an object of horror and contempt and cursing, as they are to this day—Jerusalem and the cities of Judah, its kings and officials;
Context
16Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí yóò ránṣẹ́ sí àárín wọn.” 17Mo sì gba ago náà lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó rán mi sí mu ún. 18Jerusalẹmu àti àwọn ìlú Juda, àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí. 19Farao ọba Ejibiti, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀. 20Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjèjì tí ó wà níbẹ̀;
gbogbo àwọn ọba Usi,
gbogbo àwọn ọba Filistini, gbogbo àwọn ti Aṣkeloni, Gasa, Ekroni àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Aṣdodu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.