Jeremiah 25:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí fún mi: “Gba ago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mo rán ọ sí mu ún.
Jeremiah 25:15 in English
Jeremiah 25:15 · Berean Standard Bible
This is what the LORD, the God of Israel, said to me: “Take from My hand this cup of the wine of wrath, and make all the nations to whom I send you drink from it.
Context
13Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ àní gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremiah ti sọtẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. 14Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀-èdè púpọ̀ àti àwọn ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.” 15Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí fún mi: “Gba ago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mo rán ọ sí mu ún. 16Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí yóò ránṣẹ́ sí àárín wọn.” 17Mo sì gba ago náà lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó rán mi sí mu ún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.