Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli tán. Olúwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa.

Jeremiah 24:1 in English

Jeremiah 24:1 · Berean Standard Bible

After Nebuchadnezzar king of Babylon had carried away Jeconiah * son of Jehoiakim king of Judah, as well as the officials of Judah and the craftsmen and metalsmiths from Jerusalem, and had brought them to Babylon,* the LORD showed me two baskets of figs placed in front of the temple of the LORD.

Context

1Lẹ́yìn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli tán. Olúwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa. 2Agbọ̀n kan ni èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára bí èyí tí ó tètè pọ́n; èkejì sì ní èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú rékọjá tí kò sì le è ṣe é jẹ. 3Nígbà náà ni Olúwa bi mí pé, “Kí ni ìwọ rí Jeremiah?” Mo dáhùn pe, “Èso ọ̀pọ̀tọ́.” Mo dáhùn. “Èyí tí ó dáradára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.