Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ń sọ wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa,’ èyí ni ohun tí Olúwa sọ, Ẹ̀yin ń lo ọ̀rọ̀ yìí, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún un yín láti má ṣe lò ó mọ́, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa.’

Jeremiah 23:38 in English

Jeremiah 23:38 · Berean Standard Bible

But if you claim, ‘This is the burden of the LORD,’ then this is what the LORD says: Because you have said, ‘This is the burden of the LORD,’ and I specifically told you not to make this claim,

Context

36Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dárúkọ ọ̀rọ̀ ‘ìjìnlẹ̀ Olúwa’ mọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ oníkálùkù ènìyàn di ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ̀yin ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run wa padà. 37Èyí ni ohun tí ẹ̀yin ń sọ fún wòlíì: ‘Kí ni ìdáhùn Olúwa sí ọ́?’ Tàbí ‘Kí ni ohun tí Olúwa bá ọ sọ?’ 38Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ń sọ wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa,’ èyí ni ohun tí Olúwa sọ, Ẹ̀yin ń lo ọ̀rọ̀ yìí, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún un yín láti má ṣe lò ó mọ́, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa.’ 39Nítorí náà, Èmi yóò gbàgbé yín, bẹ́ẹ̀ ni n ó lé e yín kúrò níwájú mi pẹ̀lú àwọn ìlú tí mo fi fún un yín àti àwọn baba yín. 40Èmi yóò sì mú ìtìjú ayérayé wá sí orí yín, ìtìjú tí kò ní ní ìgbàgbé.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.