Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké,” ni Olúwa wí. “Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi ṣìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n. Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ,” ni Olúwa wí.

Jeremiah 23:32 in English

Jeremiah 23:32 · Berean Standard Bible

“Indeed,” declares the LORD, “I am against those who prophesy false dreams and retell them to lead My people astray with their reckless lies. It was not I who sent them or commanded them, and they are of no benefit at all to these people,” declares the LORD.

Context

30“Nítorí náà, èmi lòdì sí àwọn wòlíì ni,” Olúwa wí, “Tí ń jí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lò lọ́dọ̀ ara wọn. 31Bẹ́ẹ̀,” ni Olúwa wí, “Èmi lòdì sí àwọn wòlíì tí wọ́n lo ahọ́n wọn káàkiri, síbẹ̀ tí wọ́n ń sọ wí pé, ‘Olúwa wí.’ 32Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké,” ni Olúwa wí. “Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi ṣìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n. Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ,” ni Olúwa wí. 33“Nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá bi ọ́ léèrè wí pé, ‘Kí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa?’ Sọ fún wọn wí pé, ‘Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ wo? Èmi yóò pa yín tì ni Olúwa wí.’ 34Bí wòlíì tàbí àlùfáà tàbí ẹnikẹ́ni bá sì gbà wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ Olúwa.’ Èmi yóò fi ìyà jẹ ọkùnrin náà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.