Jeremiah 21:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú.
Jeremiah 21:6 in English
Jeremiah 21:6 · Berean Standard Bible
I will strike down the residents of this city, both man and beast. They will die in a terrible plague.’
Context
4‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí, Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá ọba àti àwọn ará Babeli tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí. 5Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle. 6Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú. 7Olúwa sọ pé lẹ́yìn èyí, èmi yóò fi Sedekiah ọba Juda, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ènìyàn, àti àwọn tí ó kù ní ìlú yìí lọ́wọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn àti lọ́wọ́ idà, àti lọ́wọ́ ìyàn; èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti lé ọwọ́ àwọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn, òun yóò sì fi ojú idà pa wọ́n, kì yóò sì dá wọn sí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ní ìyọ́nú tàbí ṣàánú wọn.’ 8“Síwájú sí i, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.