Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kejì tí Paṣuri tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremiah sì sọ fún un wí pé, “Orúkọ Olúwa fun ọ kì í ṣe Paṣuri bí kò ṣe ìpayà.

Jeremiah 20:3 in English

Jeremiah 20:3 · Berean Standard Bible

The next day, when Pashhur released Jeremiah from the stocks, Jeremiah said to him, “The LORD does not call you Pashhur, but Magor-missabib.*

Context

1Ní ìgbà tí àlùfáà Paṣuri ọmọkùnrin Immeri olórí àwọn ìjòyè tẹmpili Olúwa gbọ́ tí Jeremiah ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí. 2Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa. 3Ní ọjọ́ kejì tí Paṣuri tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremiah sì sọ fún un wí pé, “Orúkọ Olúwa fun ọ kì í ṣe Paṣuri bí kò ṣe ìpayà. 4Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n. 5Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.