Jeremiah 18:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn, Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn. Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn ní ọjọ́ àjálù wọn.”
Jeremiah 18:17 in English
Jeremiah 18:17 · Berean Standard Bible
I will scatter them before the enemy like the east wind. I will show them My back and not My face in the day of their calamity.”
Context
15Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,
wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,
tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,
àti ọ̀nà wọn àtijọ́.
Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,
àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe. 16Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di
nǹkan ẹ̀gàn títí láé,
gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,
wọn yóò sì mi orí wọn. 17Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,
Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.
Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn
ní ọjọ́ àjálù wọn.” 18Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.” 19Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa,
gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.