Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò dé bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí.

Jeremiah 16:9 in English

Jeremiah 16:9 · Berean Standard Bible

For this is what the LORD of Hosts, the God of Israel, says: I am going to remove from this place, before your very eyes and in your days, the sounds of joy and gladness, the voices of the bride and bridegroom.

Context

7Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í ṣọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún baba tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú. 8“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àjọyọ̀ wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu. 9Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò dé bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí. 10“Nígbà tí o bá sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn yìí, tí wọ́n bá sì bi ọ́ wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe mú búburú yìí bá wa? Kí ni àṣìṣe tí àwa ṣe? Kín ni ẹ̀ṣẹ̀ tí àwa ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa?’ 11Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ fún wọn wí pé, ‘Nítorí tí àwọn baba yín ti kọ̀ mí sílẹ̀,’ ni Olúwa wí, ‘tí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn òrìṣà mìíràn tí wọ́n ń bọ, tí wọ́n ń sìn, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọn kò sì tẹ̀lé òfin mi mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.