Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Wọn yóò kú ikú ààrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú idà àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”

Jeremiah 16:4 in English

Jeremiah 16:4 · Berean Standard Bible

“They will die from deadly diseases. They will not be mourned or buried, but will lie like dung on the ground. They will be finished off by sword and famine, and their corpses will become food for the birds of the air and beasts of the earth.”

Context

2“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.” 3Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti baba wọn. 4“Wọn yóò kú ikú ààrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú idà àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.” 5Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má ṣe lọ síbẹ̀ láti káàánú tàbí ṣọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú àlàáfíà, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni Olúwa wí. 6“Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.