Jeremiah 16:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ, Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’
Jeremiah 16:14 in English
Jeremiah 16:14 · Berean Standard Bible
Yet behold, the days are coming, declares the LORD, when they will no longer say, ‘As surely as the LORD lives, who brought the Israelites up out of the land of Egypt.’
Context
12Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti ṣe búburú ju ti àwọn baba yín lọ. Wò ó bí gbogbo yín ṣe ń rìn, olúkúlùkù yín nínú agídí ọkàn búburú rẹ̀, dípò kí ẹ fi gbọ́ tèmi. 13Èmi yóò gbé yin kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí baba yín tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ rí, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti máa sìn ọlọ́run kéékèèké ní ọ̀sán àti òru nítorí èmi kì yóò fi ojúrere wò yín.’ 14“Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ, Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’ 15Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn. 16“Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.