Jeremiah 15:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí, “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn. Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run, Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.
Jeremiah 15:6 in English
Jeremiah 15:6 · Berean Standard Bible
You have forsaken Me, declares the LORD. You have turned your back. So I will stretch out My hand against you and I will destroy you; I am weary of showing compassion.
Context
4N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu. 5“Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jerusalẹmu?
Ta ni yóò dárò rẹ?
Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ? 6O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí,
“Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn.
Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run,
Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́. 7Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ,
Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà.
Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun
bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn
kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn. 8Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju
yanrìn Òkun lọ.
Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun
kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn.
Lójijì ni èmi yóò mú
ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.