Native Bible

Judges 9:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin ọmọ Jerubbaali lára Abimeleki arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣekemu, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀.

Judges 9:24 in English

Judges 9:24 · Berean Standard Bible

in order that the crime against the seventy sons of Jerubbaal might come to justice and their blood be avenged on their brother Abimelech and on the leaders of Shechem, who had helped him murder his brothers.

Context

22Lẹ́yìn tí Abimeleki ti ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́ta, 23Ọlọ́run rán ẹ̀mí búburú sáàárín Abimeleki àti àwọn ará Ṣekemu, àwọn ẹni tí ó hu ìwà ọ̀tẹ̀. 24Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin ọmọ Jerubbaali lára Abimeleki arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣekemu, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀. 25Nítorí ìkórìíra tí wọ́n ni sí àwọn olórí, ni Ṣekemu dẹ àwọn ènìyàn sí àwọn orí òkè láti máa dá àwọn ènìyàn tó ń kọjá lọ́nà, kí wọn sì máa jà wọ́n lólè, àwọn kan ló sọ èyí fún Abimeleki. 26Gaali ọmọ Ebedi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣekemu, àwọn ará Ṣekemu sì gbẹ́kẹ̀lé wọn, wọ́n sì fi inú tán wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.