Onidajọ 8:9
Judges 8:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Penieli pé, “Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé ní àlàáfíà, èmi yóò wó ilé ìṣọ́ yìí.”
Judges 8:9 in English
Judges 8:9 · Berean Standard Bible
So Gideon told the men of Penuel, “When I return in triumph, I will tear down this tower!”
Context
7Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Ó dára, nígbà tí Olúwa bá fi Seba àti Salmunna lé mi lọ́wọ́ tán èmi yóò fi ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún òṣùṣú ya ẹran-ara yín.” 8Láti ibẹ̀, ó lọ sí Penieli ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Sukkoti ti dá a lóhùn. 9Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Penieli pé, “Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé ní àlàáfíà, èmi yóò wó ilé ìṣọ́ yìí.” 10Ní àsìkò náà Seba àti Salmunna wà ní Karkori pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn, nítorí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun. 11Gideoni gba ọ̀nà tí àwọn darandaran máa ń rìn ní apá ìhà ìlà-oòrùn Noba àti Jogbeha ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ-ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.